قُلِ ٱدۡعُواْ ٱللَّهَ أَوِ ٱدۡعُواْ ٱلرَّحۡمَٰنَۖ أَيّٗا مَّا تَدۡعُواْ فَلَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَلَا تَجۡهَرۡ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتۡ بِهَا وَٱبۡتَغِ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلٗا ١١٠
Qulid'ullāha awid'ur-rahmāna ayyam mā tad'ū falahul-asmā'ul-husnā walā tajhar bisalātika walā tukhāfit bihā wabtaghi bayna dhālika sabīlā
Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).”1 Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Pípe Allāhu tàbí ar-Rahmọ̄n tàbí èyíkéyìí nínú àwọn orúkọ Allāhu tí ó dára jùlọ, kò túmọ̀ sí fífa orúkọ kan nínú àwọn orúkọ Allāhu pẹ̀lú òǹkà púpọ̀ bíi sísọ pé Allāhu, Allāhu … tàbí ar-Rahmọ̄n, ar-Rahmọ̄n … Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìlànà àwọn onibid‘ah. Èyí tí ó tọ sunnah ni lílo àwọn orúkọ náà nínú gbólóhùn.