Suratu Al-Baqarah, aaya 273

2:273

لِلۡفُقَرَآءِ ٱلَّذِينَ أُحۡصِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا يَسۡتَطِيعُونَ ضَرۡبٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ يَحۡسَبُهُمُ ٱلۡجَاهِلُ أَغۡنِيَآءَ مِنَ ٱلتَّعَفُّفِ تَعۡرِفُهُم بِسِيمَٰهُمۡ لَا يَسۡـَٔلُونَ ٱلنَّاسَ إِلۡحَافٗاۗ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٌ ٢٧٣

Lil-fuqarā'il-ladhīna uhsirū fī sabīlillāhi lā yastatī'ūna darban fil-ardi yahsabuhumul-jāhilu aghniyā'a minat-ta'affufi ta'rifuhum bisīmāhum lā yas'alūnan-nāsa ilhāfan wamā tunfiqū min khayrin fa innallāha bihī 'alīm

(Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí kí wọ́n lè máa jagun) sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́.1 Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àwọn aláìní wọ̀nyẹn ni a mọ̀ sí ahlus-suffah. Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ nípa wọn nínú sūrah al-’An‘ām; 6:52 àti sūrah al-Kahf; 18:28.