Suratu Al-Baqarah, aaya 194

2:194

ٱلشَّهۡرُ ٱلۡحَرَامُ بِٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ وَٱلۡحُرُمَٰتُ قِصَاصٞۚ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَٱعۡتَدُواْ عَلَيۡهِ بِمِثۡلِ مَا ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ ١٩٤

Ash-shahrul-harāmu bish-shahril-harāmi wal-hurumātu qisāsun famani'tadā 'alaykum fa'tadū 'alayhi bimithli ma'tadā 'alaykum wattaqullāha wa'lamū annallāha ma'al-muttaqīn

Oṣù ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àwọn n̄ǹkan ọ̀wọ̀ sì ní (òfin) ìgbẹ̀san.1 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà si yín, ẹ gb’ẹ̀san ìtayọ ẹnu-ààlà lára rẹ̀ pẹ̀lú irú ohun tí ó fi tayọ ẹnu-ààlà si yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, ìpìlẹ̀ lọ́dọ̀ àwa mùsùlùmí ni bíbu ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àmọ́ tí àwọn kèfèrí bá dá ogun sílẹ̀ nínú oṣù ọ̀wọ̀, ẹ má ṣe káwọ́ gbera, ẹ ja àwọn náà lógun.