Suratu Al-A'raf, aaya 101

7:101

تِلۡكَ ٱلۡقُرَىٰ نَقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآئِهَاۚ وَلَقَدۡ جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا كَانُواْ لِيُؤۡمِنُواْ بِمَا كَذَّبُواْ مِن قَبۡلُۚ كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ١٠١

Tilkal-qurā naqussu 'alayka min ambā'ihā walaqad jā'athum rusuluhum bil-bayyināti famā kānū liyu'minū bimā kaddhabū min qablu kadhālika yatba'ullāhu 'alā qulūbil-kāfirīn

Àwọn ìlú wọ̀nyí ni À ń fún ọ ní ìró nínú ìròyìn wọn. Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ wọn ti mú àwọn ẹ̀rí tó yánjú wá bá wọn. (Ìkọ̀ọ̀kan ìjọ náà,) wọn kò kúkú níí gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ tó ṣíwájú wọn) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó ṣíwájú ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn aláìgbàgbọ́ tó tẹ̀lé wọn ṣe. Irú kan-ùn ni gbogbo wọn. Ìdí sì nìyí tí ìkọ̀ọ̀kan ìjọ aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn ṣe parun. Ẹ tún wo sūrah Yūnus; 10:74.