Suratu Al-Anfal, aaya 67

8:67

مَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَن يَكُونَ لَهُۥٓ أَسۡرَىٰ حَتَّىٰ يُثۡخِنَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ تُرِيدُونَ عَرَضَ ٱلدُّنۡيَا وَٱللَّهُ يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٞ ٦٧

Mā kāna linabiyyin an yakūna lahū asrā hattā yuthkhina fil-ardi turīdūna 'aradad-dunyā wallāhu yurīdul-ākhirata wallāhu 'azīzun hakīm

Kò yẹ fún Ànábì kan láti ní ẹrú ogun títí ọwọ́ rẹ̀ máa fi ba àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí ilẹ̀ dáadáa ní ti pípa.1 Ẹ̀yin ń fẹ́ ìgbádùn ayé, Allāhu sì ń fẹ́ ọ̀run. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.