Wa man yattaqillaha yaj'al lahu makhraja

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

فَإِذَا بَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمۡسِكُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ فَارِقُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٖ وَأَشۡهِدُواْ ذَوَيۡ عَدۡلٖ مِّنكُمۡ وَأَقِيمُواْ ٱلشَّهَٰدَةَ لِلَّهِۚ ذَٰلِكُمۡ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ وَمَن يَتَّقِ ٱللَّهَ يَجۡعَل لَّهُۥ مَخۡرَجٗا ٢

Fa idhā balaghna ajalahunna fa amsikūhunna bima'rūfin aw fāriqūhunna bima'rūfin wa ashhidū dhaway 'adlim minkum wa aqīmush-shahādata lillāhi dhālikum yū'azu bihī man kāna yu'minu billāhi wal-yawmil-ākhiri waman yattaqillāha yaj'al lahū makhrajā

Nígbà tí wọ́n bá fẹ́ parí òǹkà ọjọ́ opó wọn, ẹ mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà tó dára tàbí kí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní ọ̀nà tó dára.1 Ẹ fi àwọn onídéédé méjì nínú yín jẹ́rìí sí i. Kí ẹ sì gbé ìjẹ́rìí náà dúró ní tìtorí ti Allāhu. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bẹ̀rù Allāhu, Ó máa fún un ní ọ̀nà àbáyọ (nínú ìṣòro).

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, ẹ lè dá gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ pada (ìyẹn tí ìkọ̀sílẹ̀ kò bá tí ì pé ìgbà mẹ́ta) tàbí ẹ sì lè takú sórí gbólóhùn ìkọ̀sílẹ̀ náà títí òǹkà n̄ǹkan oṣù mẹ́ta yóò fi ko sẹ̀.

وَيَرۡزُقۡهُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَحۡتَسِبُۚ وَمَن يَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِ فَهُوَ حَسۡبُهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَٰلِغُ أَمۡرِهِۦۚ قَدۡ جَعَلَ ٱللَّهُ لِكُلِّ شَيۡءٖ قَدۡرٗا ٣

Wayarzuqhu min haythu lā yahtasibu waman yatawakkal 'alallāhi fahuwa hasbuhū innallāha bālighu amrihī qad ja'alallāhu likulli shay'in qadrā

Ó sì máa pèsè fún un ní àyè tí kò ti rokàn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Allāhu, Ó máa tó o. Dájúdájú Allāhu yóò mú àṣẹ Rẹ̀ ṣẹ. Dájúdájú Allāhu ti kọ òdíwọ̀n àkókò fún gbogbo n̄ǹkan.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Ka gbogbo Suratu At-Talaq

Àwọn ìbéèrè

Níbo ni Wa man yattaqillaha yaj'al lahu makhraja wà nínú Al-Kurani?

Wa man yattaqillaha yaj'al lahu makhraja wà nínú Suratu At-Talaq, 65:2-3.