La ikraha fid-din

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

لَآ إِكۡرَاهَ فِي ٱلدِّينِۖ قَد تَّبَيَّنَ ٱلرُّشۡدُ مِنَ ٱلۡغَيِّۚ فَمَن يَكۡفُرۡ بِٱلطَّٰغُوتِ وَيُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱسۡتَمۡسَكَ بِٱلۡعُرۡوَةِ ٱلۡوُثۡقَىٰ لَا ٱنفِصَامَ لَهَاۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ ٢٥٦

Lā ikrāha fid-dīni qat tabayyanar-rushdu minal-ghayyi faman yakfur bit-tāghūti wayu'mim billāhi faqadistamsaka bil-'urwatil-wuthqā lanfisāma lahā wallāhu samī'un 'alīm

Kò sí ìjẹnípá nínú ẹ̀sìn. Ìmọ̀nà ti fojú hàn kúrò nínú ìṣìnà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn tó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Ka gbogbo Suratu Al-Baqarah

Àwọn ìbéèrè

Níbo ni La ikraha fid-din wà nínú Al-Kurani?

La ikraha fid-din wà nínú Suratu Al-Baqarah, 2:256.