La ilaha illa anta subhanaka

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

وَذَا ٱلنُّونِ إِذ ذَّهَبَ مُغَٰضِبٗا فَظَنَّ أَن لَّن نَّقۡدِرَ عَلَيۡهِ فَنَادَىٰ فِي ٱلظُّلُمَٰتِ أَن لَّآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنتَ سُبۡحَٰنَكَ إِنِّي كُنتُ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ ٨٧

Wadhan-nūni id dhahaba mughādiban fazanna al lan naqdira 'alayhi fanādā fiz-zulumāti al lā ilāha illā anta subhānaka innī kuntu minaz-zālimīn

(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi wà nínú àwọn alábòsí.”1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Kíyè sí i, ohun tí Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - kà kún àbòsí nínú àdúà rẹ̀ yìí kì í ṣe ìjàǹbá nítorí pé, kò sí Ànábì tó jẹ́ oníjàǹbá. Àmọ́ ohun tí ó ṣe ni pé, ó kánjú kúrò láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n tọrọ ìyà, tí ìyà náà sì fẹ́ sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí. Nítorí kí ìyà má baà kó òun náà sínú ló fi kánjú yẹra fún wọn.

فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ وَنَجَّيۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡغَمِّۚ وَكَذَٰلِكَ نُـۨجِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٨٨

Fastajabnā lahū wanajjaynāhu minal-ghammi wakadhālika nujil-mu'minīn

A jẹ́pè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Ka gbogbo Suratu Al-Anbiya

Àwọn ìbéèrè

Níbo ni La ilaha illa anta subhanaka wà nínú Al-Kurani?

La ilaha illa anta subhanaka wà nínú Suratu Al-Anbiya, 21:87-88.