Suratu At-Tawbah, aaya 115

9:115

وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِلَّ قَوۡمَۢا بَعۡدَ إِذۡ هَدَىٰهُمۡ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُم مَّا يَتَّقُونَۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ ١١٥

Wamā kānallāhu liyudilla qawmā ba'da idh hadāhum hattā yubayyina lahum mā yattaqūna innallāha bikulli shay'in 'alīm

Allāhu kì í mú ìṣìnà bá ìjọ kan, lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti tọ́ wọn sọ́nà, títí (Allāhu) yóò fi ṣe àlàyé n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣọ́ra fún fún wọn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, à ò níí pe mùsùlùmí ní olùṣìnà bí ó bá ṣe n̄ǹkan tí kò yẹ kí ó ṣe níwọ̀n ìgbà tí kò ì sí ẹ̀rí kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu tí ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un àfi lẹ́yìn ìgbà tí ẹ̀rí bá dé bá a, tí ó tún wá ń ṣe n̄ǹkan náà lọ.