لِلَّذِينَ ٱسۡتَجَابُواْ لِرَبِّهِمُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَٱلَّذِينَ لَمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَهُۥ لَوۡ أَنَّ لَهُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا وَمِثۡلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفۡتَدَوۡاْ بِهِۦٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ سُوٓءُ ٱلۡحِسَابِ وَمَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ ١٨
Lilladhīnastajābū lirabbihimul-husnā walladhīna lam yastajībū lahū law anna lahum mā fil-ardi jamī'an wamithlahū ma'ahū laftadaw bihī ulā'ika lahum sū'ul-hisābi wama'wāhum jahannamu wabi'sal-mihād
Ohun rere (ìyẹn Ọgbà Ìdẹ̀ra) wà fún àwọn tó jẹ́pè Olúwa wọn. Àwọn tí kò sì jẹ́pè Rẹ̀, tí ó bá jẹ́ pé tiwọn ni gbogbo n̄ǹkan tó ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá àti irú rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni aburú ìṣírò-iṣẹ́ wà fún.1 Iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn; ibùgbé náà sì burú.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Aburú ìṣírò-iṣẹ́ ni kí Allāhu kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá lé e lọ́wọ́, kí Ó má ṣàforíjìn fún un nítorí pé, ẹ̀dá náà kú sórí ẹbọ ṣíṣe tàbí àìgbàgbọ́ tàbí ìṣọ̀bẹ-ṣèlu àfọkànṣe.