لَّا تَجۡعَلُواْ دُعَآءَ ٱلرَّسُولِ بَيۡنَكُمۡ كَدُعَآءِ بَعۡضِكُم بَعۡضٗاۚ قَدۡ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ يَتَسَلَّلُونَ مِنكُمۡ لِوَاذٗاۚ فَلۡيَحۡذَرِ ٱلَّذِينَ يُخَالِفُونَ عَنۡ أَمۡرِهِۦٓ أَن تُصِيبَهُمۡ فِتۡنَةٌ أَوۡ يُصِيبَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ ٦٣
Llā taj'alū du'ā'ar-rasūli baynakum kadu'ā'i ba'dikum ba'dan qad ya'lamullāhul-ladhīna yatasallalūna minkum liwādhan falyahdharil-ladhīna yukhālifūna 'an amrihī an tusībahum fitnatun aw yusībahum 'adhābun alīm
Ẹ má ṣe ládìsọ́kàn pé ìpè Òjíṣẹ́1 láààrin yín dà bí ìpè apá kan fún apá kan. Allāhu kúkú ti mọ àwọn tó ń yọ́ sá lọ nínú yín. Nítorí náà, kí àwọn tó ń yapa àṣẹ rẹ̀ ṣọ́ra nítorí kí ìdààmú má baà dé bá wọn, tàbí nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baá jẹ wọ́n.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìtúmọ̀ mẹ́ta ló wà fún ìpè Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. (1) Kí Òjíṣẹ́ pe àwọn Sọhābah rẹ̀ fún ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn; ìyẹn ni pé, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́pè Òjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. (2) Kí Sọhābah kan pe Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pẹ̀lú orúkọ rẹ̀; ìyẹn ni pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lórúkọ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń pe ara yín. Ẹ gbọ́dọ̀ dà á pè. (3) Kí Òjíṣẹ́ ṣẹ́bilé ẹ̀dá kan; ìyẹn ni pé, ẹ ṣọ́ra fún èpè Òjíṣẹ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.