وَلۡيَسۡتَعۡفِفِ ٱلَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغۡنِيَهُمُ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦۗ وَٱلَّذِينَ يَبۡتَغُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِمَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُمۡ فَكَاتِبُوهُمۡ إِنۡ عَلِمۡتُمۡ فِيهِمۡ خَيۡرٗاۖ وَءَاتُوهُم مِّن مَّالِ ٱللَّهِ ٱلَّذِيٓ ءَاتَىٰكُمۡۚ وَلَا تُكۡرِهُواْ فَتَيَٰتِكُمۡ عَلَى ٱلۡبِغَآءِ إِنۡ أَرَدۡنَ تَحَصُّنٗا لِّتَبۡتَغُواْ عَرَضَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَن يُكۡرِههُّنَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ مِنۢ بَعۡدِ إِكۡرَٰهِهِنَّ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ٣٣
Walyasta'fifil-ladhīna lā yajidūna nikāhan hattā yughniyahumullāhu min fadlihī walladhīna yabtaghūnal-kitāba mimmā malakat aymānukum fakātibūhum in 'alimtum fīhim khayran wa ātūhum mim mālillāhil-ladhī ātākum walā tukrihū fatayātikum 'alal-bighā'i in aradna tahassunal litabtaghū 'aradal-hayawātid-dunyā waman yukrihhunna fa innallāha mim ba'di ikrāhihinna ghafūrur rahīm
Kí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.1 Àwọn tó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fún yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.2 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá.3
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Kò sí ìtakora láààrin gbólóhùn yìí “Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.” àti gbólóhùn yìí. “Kí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.” Gbólóhùn kìíní ń kìlọ̀ fún wa láti jìnnà sí fífí ọmọ fún olówó nìkan. Gbólóhùn kejì sì ń kìlọ̀ fún wa láti jìnnà sí fífi ìyàwó fún ẹni tí kò ní ọ̀nà kan kan láti máa fi bọ́ ìyàwó. [2] Awẹ́ gbólóhùn “tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.” kì í ṣe májẹ̀mu fún awẹ́ gbólóhùn tó ṣíwájú. Ìyẹn ni pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe lérò pé bí ẹrúbìnrin kò bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ rẹ̀, olówó rẹ̀ lè rán an lọ ṣe sìná wá. Rárá o. Àfijọ ọ̀rọ̀ yìí dà bí awẹ́ gbólóhùn “èyí tó ń bẹ nínú ilé yín…” - sūrah an-Nisā; 4:23 - . Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah náà. [3] Ìyẹn fún ẹrúbìnrin tí olówó rẹ̀ jẹ nípá láti lọ ṣe sìná.