Suratu An-Nisa, aaya 79

4:79

مَّآ أَصَابَكَ مِنۡ حَسَنَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ وَمَآ أَصَابَكَ مِن سَيِّئَةٖ فَمِن نَّفۡسِكَۚ وَأَرۡسَلۡنَٰكَ لِلنَّاسِ رَسُولٗاۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدٗا ٧٩

Mmā asābaka min hasanatin faminallāhi wamā asābaka min sayyi'atin famin nafsika wa arsalnāka lin-nāsi rasūlan wakafā billāhi shahīdā

Ohunkóhun tó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Èbùbù, àyànmọ́ àti kádàrá ń túmọ̀ ara wọn. Ohun rere tí ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ àti aburú tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láyé àti lọ́run pẹ̀lú ọ̀nà tí ó máa gbà ṣẹlẹ̀ ni kìkìdá kádàrá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.