لَّا تَجِدُ قَوۡمٗا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ يُوَآدُّونَ مَنۡ حَآدَّ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَوۡ كَانُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ أَوۡ أَبۡنَآءَهُمۡ أَوۡ إِخۡوَٰنَهُمۡ أَوۡ عَشِيرَتَهُمۡۚ أُوْلَٰٓئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَأَيَّدَهُم بِرُوحٖ مِّنۡهُۖ وَيُدۡخِلُهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ رَضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُۚ أُوْلَٰٓئِكَ حِزۡبُ ٱللَّهِۚ أَلَآ إِنَّ حِزۡبَ ٱللَّهِ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ ٢٢
Llā tajidu qawman yu'minūna billāhi wal-yawmil-ākhiri yuwāddūna man hāddallāha warasūlahū walaw kānū ābā'ahum aw abnā'ahum aw ikhwānahum aw 'ashīratahum ulā'ika kataba fī qulūbihimul-īmāna wa ayyadahum birūhim minhu wayudkhiluhum jannātin tajrī min tahtihal-anhāru khālidīna fīhā radiyallāhu 'anhum waradū 'anhu ulā'ika hizbullāhi alā inna hizballāhi humul-muflihūn
O ò níí rí ìjọ kan tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kódà kí wọ́n jẹ́ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ìbátan wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ti kọ ìgbàgbọ́ òdodo sínú ọkàn wọn. Allāhu sì fi ẹ̀rí òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.1 Ó sì máa mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Allāhu. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùjèrè.2
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Kíyè sí i! Ìtúmọ̀ “rūh” nínú āyah yìí ni ẹ̀rí òdodo, ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà. Àmọ́ ìtúmọ̀ “rūh” nínú sūrah an-Nisā’; 4:171, ìyẹn túmọ̀ sí ẹ̀mí tí Allāhu Ẹlẹ́dàá fi dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Bákan náà, “minhu” tí ó wà pẹ̀lú “rūh” nínú àwọn āyah méjèèjì túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni ẹ̀rí òdodo (ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà) àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti wá. Iṣẹ́ ọwọ́ Allāhu sì ni àwọn méjèèjì. Irú “minhu” yìí náà ló wà nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:13. Ìyẹn ni pé, “min” tí ó túmọ̀ sí “kí n̄ǹkan wá láti ibì kan”, kì í ṣe “min” tí ó túmọ̀ sí “kí n̄ǹkan jẹ́ ara kan-ùn”.
2 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah at-Taobah; 9:23.