قَالَ ذَٰلِكَ مَا كُنَّا نَبۡغِۚ فَٱرۡتَدَّا عَلَىٰٓ ءَاثَارِهِمَا قَصَصٗا ٦٤
Qāla dhālika mā kunnā nabghi fartaddā 'alā āthārihimā qasasā
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Ibi tí ẹja ti lọ) yẹn ni ohun tí à ń wá.”1 Àwọn méjèèjì sì padà sẹ́yìn láti tọ orípa ẹsẹ̀ wọn bí wọ́n ti ṣe tọ̀ ọ́ wá.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọ fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - tẹ́lẹ̀ pé, ibi tí wọ́n bá gbàgbé ẹja sí, ibẹ̀ ni wọ́n máa ti pàdé ẹni tí ó ń lọ ṣàbẹ̀wò rẹ̀.