Suratu Al-Isra, aaya 42

17:42

قُل لَّوۡ كَانَ مَعَهُۥٓ ءَالِهَةٞ كَمَا يَقُولُونَ إِذٗا لَّٱبۡتَغَوۡاْ إِلَىٰ ذِي ٱلۡعَرۡشِ سَبِيلٗا ٤٢

Qul law kāna ma'ahū ālihatun kamā yaqūlūna idhal labtaghaw ilā dhil-'arshi sabīlā

Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́hun kan tún wà pẹ̀lú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń wí, wọn ìbá wá ọ̀nà láti súnmọ́ (Allāhu) Onítẹ̀ẹ́-ọlá ni.”1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, àwọn òrìṣà gan-an ń wá oore sọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.