Suratu Al-Imran, aaya 81

3:81

وَإِذۡ أَخَذَ ٱللَّهُ مِيثَٰقَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ لَمَآ ءَاتَيۡتُكُم مِّن كِتَٰبٖ وَحِكۡمَةٖ ثُمَّ جَآءَكُمۡ رَسُولٞ مُّصَدِّقٞ لِّمَا مَعَكُمۡ لَتُؤۡمِنُنَّ بِهِۦ وَلَتَنصُرُنَّهُۥۚ قَالَ ءَأَقۡرَرۡتُمۡ وَأَخَذۡتُمۡ عَلَىٰ ذَٰلِكُمۡ إِصۡرِيۖ قَالُوٓاْ أَقۡرَرۡنَاۚ قَالَ فَٱشۡهَدُواْ وَأَنَا۠ مَعَكُم مِّنَ ٱلشَّٰهِدِينَ ٨١

Wa idh akhadhallāhu mīthāqan-nabiyyina lamā ātaytukum min kitābin wahikmatin thumma jā'akum rasūlum musaddiqul limā ma'akum latu'minunna bihī walatansurunnahū qāla a'aqrartum wa akhadhtum 'alā dhālikum isrī qālū aqrarnā qāla fashhadū wa ana ma'akum minash-shāhidīn

(Ẹ rántí) nígbà tí Allāhu gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn Ànábì1 pé: “Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí nígbà tí Mo bá fún yín ní tírà àti òye ìjìnlẹ́, lẹ́yìn náà Òjíṣẹ́ kan (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yóò dé ba yín; ó máa fi èyí tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ẹ gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́, ẹ sì gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́.” (Allāhu) sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ gbà? Ṣé ẹ sì máa lo àdéhùn Mi yìí?” Wọ́n sọ pé: “A gbà.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ jẹ́rìí sí (àdéhùn náà). Èmi ń bẹ pẹ̀lú yín nínú àwọn Olùjẹ́rìí.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àdéhùn yìí wà fún Ànábì kọ̀ọ̀kan àti ìjọ rẹ̀, pé kí wọ́n máa lo iṣẹ́ tí Ànábì wọn bá jẹ́ fún wọn títí Ànábì ìkẹ́yìn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yóò fi dé.