Suratu Al-Imran, aaya 28

3:28

لَّا يَتَّخِذِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۖ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَلَيۡسَ مِنَ ٱللَّهِ فِي شَيۡءٍ إِلَّآ أَن تَتَّقُواْ مِنۡهُمۡ تُقَىٰةٗۗ وَيُحَذِّرُكُمُ ٱللَّهُ نَفۡسَهُۥۗ وَإِلَى ٱللَّهِ ٱلۡمَصِيرُ ٢٨

Llā yattakhidhil-mu'minūnal-kāfirīna awliyā'a min dūnil-mu'minīna waman yaf'al dhālika falaysa minallāhi fī shay'in illā an tattaqū minhum tuqātan wayuhaddhirukumullāhu nafsahū wa ilallāhil-masīr

Àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò gbọ́dọ̀ sọ àwọn aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò (ọ̀rẹ́ finúhannú) lẹ́yìn àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ẹgbẹ́ wọn). Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìyẹn, kò sí kiní kan fún un mọ́ lọ́dọ̀ Allāhu.1 Àfi tí ẹ bá ń (fi ọ̀rẹ́ orí ahọ́n) wá ìṣọ́ra lọ́dọ̀ wọn) dáadáa (lórí ìgbàgbọ́ yín).2 Allāhu ń kìlọ̀ ara Rẹ̀ fún yín. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ẹni tí ó sọ aláìgbàgbọ́ di ọ̀rẹ́ àyò tí yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ Allāhu, Allāhu sì ti yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. [2] Ìyẹn fún àwọn mùsùlùmí tí ń bẹ lábẹ́ àṣẹ àti ìdàrí àwọn aláìgbàgbọ́ bí ó bá la làlúrí lọ.