Suratu Al-Baqarah, aaya 48

2:48

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡـٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا يُؤۡخَذُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ٤٨

Wattaqū yawmal lā tajzī nafsun 'an nafsin shay'an walā yuqbalu minhā shafā'atun walā yu'khadhu minhā 'adlun walā hum yunsarūn

Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.1 Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, l’ọ́jọ́ Àjíǹde dúkìá kan kan kò níí wúlò fún ìràpadà ẹ̀mí níbi Iná àfi iṣẹ́ rere tí í ṣe ìjọ́sìn fún Allāhu àti ìwà rere tó tọ sunnah.