لِّلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَإِن تُبۡدُواْ مَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ أَوۡ تُخۡفُوهُ يُحَاسِبۡكُم بِهِ ٱللَّهُۖ فَيَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ ٢٨٤
Lillāhi mā fis-samāwāti wamā fil-ardi wa in tubdū mā fī anfusikum aw tukhfūhu yuhāsibkum bihillāhu fayaghfiru liman yashā'u wayu'addhibu man yashā'u wallāhu 'alā kulli shay'in qadīr
Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun tó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fún yín1. Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Gbólóhùn yìí ba àwọn Sọhābah nínú jẹ́ gidigidi, àmọ́ Allāhu dẹ̀ ẹ́ fún wọn nínú āyah tí ó parí sūrah yìí.