Suratu Al-A'raf, aaya 190

7:190

فَلَمَّآ ءَاتَىٰهُمَا صَٰلِحٗا جَعَلَا لَهُۥ شُرَكَآءَ فِيمَآ ءَاتَىٰهُمَاۚ فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ عَمَّا يُشۡرِكُونَ ١٩٠

Falammā ātāhumā sālihan ja'alā lahū shurakā'a fīmā ātāhumā fata'ālallāhu 'ammā yushrikūn

Ṣùgbọ́n nígbà tí Allāhu fún àwọn méjèèjì ní ọmọ rere, wọ́n sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Un nípasẹ̀ ohun tí Ó fún àwọn méjèèjì. Allāhu sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ẹbọ tí wọ́n ṣe nípasẹ̀ ọmọ wọn ni sísọ ọmọ náà ni orúkọ tí ó fi àìmoore hàn sí Allāhu. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí Allāhu fún ènìyàn lọ́mọ, kí ènìyàn wá sọ ọmọ náà ni “ ‘abdu-ṣṣams, ‘abdul-ƙọmọr” dípò “ ‘abdullāh, ‘abdur-Rahmọ̄n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.