Suratu Al-Ahzab, aaya 52

33:52

لَّا يَحِلُّ لَكَ ٱلنِّسَآءُ مِنۢ بَعۡدُ وَلَآ أَن تَبَدَّلَ بِهِنَّ مِنۡ أَزۡوَٰجٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَكَ حُسۡنُهُنَّ إِلَّا مَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ رَّقِيبٗا ٥٢

Llā yahillu lakan-nisā'u mim ba'du walā an tabaddala bihinna min azwājin walaw a'jabaka husnuhunna illā mā malakat yamīnuka wakānallāhu 'alā kulli shay'ir raqībā

Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ (láti fẹ́) àwọn obìnrin (mìíràn) lẹ́yìn (ìsọ̀rí àwọn obìnrin tí A ti sọ ṣíwájú1, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún ọ) láti fi àwọn obìnrin (mìíràn) pààrọ̀ wọn, kódà kí dáadáa wọn jọ ọ́ lójú, àfi àwọn ẹrú rẹ. Allāhu sì ń jẹ́ Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.2

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn nínú āyah 50. [2] Āyah yìí kò túmọ̀ sí pé kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - má ṣe fẹ́ ìyàwó kún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní àsìkò tí āyah yìí sọ̀kalẹ̀, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ fẹ́ obìnrin kan àyàfi nínú àwọn ìsọ̀rí obìnrin tí Allāhu ti ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un nínú āyah 50.