Suratu Yusuf, aaya 106

12:106

وَمَا يُؤۡمِنُ أَكۡثَرُهُم بِٱللَّهِ إِلَّا وَهُم مُّشۡرِكُونَ ١٠٦

Wamā yu'minu aktharuhum billāhi illā wahum mushrikūn

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni kò níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àfi kí wọ́n tún máa ṣẹbọ.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, àwọn ènìyàn kan ń bẹ láààrin àwa mùsùlùmí tí ó jẹ́ pé, tòhun ti bí wọ́n ṣe ń ṣe ’Islām, wọ́n tún ń ṣẹbọ yálà ní kọ̀rọ̀ tàbí ní gban̄gba. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, “mùsùlùmí” tó ń lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, páítọ̀ àti babaláwo, “mùsùlùmí” tí ó ń pe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, “mùsùlùmí” tí ó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, “mùsùlùmí” tí ó ń bọ àwọn òrìṣà bí òrìṣà egúngún, òrìṣà ìbejì, òrìṣà Ajé àti “mùsùlùmí” tí ó ń lo ìfúnpá àti àsorọ̀ òògùn àti àsorọ̀ tíà àti “mùsùlùmí” tí ó ń gbé ẹbọ àti ètùtù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì í ṣe mùsùlùmí ní ọ̀dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ.