Suratu Yunus, aaya 94

10:94

فَإِن كُنتَ فِي شَكّٖ مِّمَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ فَسۡـَٔلِ ٱلَّذِينَ يَقۡرَءُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكَۚ لَقَدۡ جَآءَكَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ ٩٤

Fa in kunta fī shakkim mimmā anzalnā ilayka fas'alil-ladhīna yaqra'ūnal-kitāba min qablika laqad jā'akal-haqqu mir rabbika falā takūnanna minal-mumtarīn

Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú at-Taorāt àti al-’Injīl), bi àwọn tó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò.1 Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ gba ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ àwọn onítírà, àmọ́ láti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ pé, Allāhu ló fi iṣẹ́ rán gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò sì níí sí ìtakora nínú àwọn iṣẹ́ náà.