Suratu Yunus, aaya 62

10:62

أَلَآ إِنَّ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ٦٢

Alā inna awliyā'allāhi lā khawfun 'alayhim walā hum yahzanūn

Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé).1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Nínú èdè Lárúbáwá, ìtúmọ̀ “waliyyu” pọ̀. Nínú rẹ̀ ni ìwọ̀nyí; ọ̀rẹ́, alásùn-únmọ́, ọ̀rẹ́ àyò, alámòójútó, aláṣẹ, aláàbò, aláfẹ̀yìntì, alárànṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo àwọn ìtúmọ̀ wọ̀nyí ló so pọ̀ mọ́ra wọn.