وَءَايَةٞ لَّهُمُ ٱلَّيۡلُ نَسۡلَخُ مِنۡهُ ٱلنَّهَارَ فَإِذَا هُم مُّظۡلِمُونَ ٣٧
Wa āyatul lahumul-laylu naslakhu minhun-nahāra fa idhā hum muzlimūn
Àmì kan ni òru jẹ́ fún wọn, tí À ń yọ ọ̀sán jáde láti inú rẹ̀. Nígbà náà (tí A bá yọ ọ́ tán) wọn yóò tún wà nínú òkùnkùn (alẹ́ mìíràn).1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Kókó inú āyah yìí ni pé, òru l’ó ń ṣíwájú ọ̀sán nínú ọjọ́, bí àpẹ̀ẹrẹ, òru Jum'ah mọ́júmọ́ ọ̀sán Jum'ah, òru Sabt mọ́júmọ́ ọ̀sán Sabt. Nítorí náà, kò sí òru Àlàmísì mọ́júmọ́ ọ̀sán Jímọ̀. Kò sì sí òru Jímọ̀ mọ́júmọ́ Sabt.