يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ قَدۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ عَدُوِّكُمۡ وَوَٰعَدۡنَٰكُمۡ جَانِبَ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنَ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰ ٨٠
Yābanī isrā'īla qad anjaynākum min 'aduwwikum wawā'adnākum jānibat-tūril-aymana wanazzalnā 'alaykumul-manna was-salwā
Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ṣe àdéhùn fún yín (pé kí Ànábì Mūsā wá, kí Á bá a sọ̀rọ̀ tààrà) ní ẹ̀gbẹ́ àpáta ní ọwọ́ ọ̀tún1 (Ànábì Mūsā láààrin àpáta àti àfonífojì2 ní ìwọ̀ òòrùn3). A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fún yín.4
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, ìjúwe àpáta ibi tí Allāhu - tó ga jùlọ - ti bá Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - sọ̀rọ̀ tààrà nìyí, ó gbé àpáta sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àfonífojì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀ ní àgbègbè ìwọ̀-òòrùn ìlú náà. [2] Sūrah al-Ƙọsọs; 28:30 [3] Sūrah al-Ƙọsọs; 28:40 [4] Ìyẹn ni oúnjẹ wọn lórí ìrìn àrìnnù ológójì ọdún. Ẹ wo sūrah al-Mọ̄’idah 5:26.