وَحِيلَ بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ مَا يَشۡتَهُونَ كَمَا فُعِلَ بِأَشۡيَاعِهِم مِّن قَبۡلُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ فِي شَكّٖ مُّرِيبِۭ ٥٤
Wahīla baynahum wabayna mā yashtahūna kamā fu'ila bi ashyā'ihim min qablu innahum kānū fī shakkim murīb
A sì fi gàgá sí ààrin àwọn àti ohun tí wọ́n ń ṣojú kòkòrò rẹ̀1 gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe fún àwọn ẹgbẹ́ wọn ní ìṣáájú. Dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì tó gbópọn (nípa Ọjọ́ Àjíǹde).
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àwọn aláìgbàgbọ́ yóò máa ṣojú kòkòrò sí ìronúpìwàdà àti ìpadà sí ilé ayé ní Ọjọ́ Àjíǹde nígbà tí àìgbàgbọ́ wọn bá di ìyà ńlá fún wọn. Àmọ́ Allāhu kò níí fún wọn ní àyè láti lọ ronú pìwàdà tàbí láti padà sí ilé ayé.