Suratu Luqman, aaya 6

31:6

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَشۡتَرِي لَهۡوَ ٱلۡحَدِيثِ لِيُضِلَّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَيَتَّخِذَهَا هُزُوًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ ٦

Waminan-nāsi man yashtarī lahwal-hadīthi liyudilla 'an sabīlillāhi bighayri 'ilmin wayattakhidhahā huzuwan ulā'ika lahum 'adhābum muhīn

Ó wà nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ra ọ̀rọ̀ eré1 láti fi ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àìnímọ̀ àti nítorí kí ó lè sọ ẹ̀sìn di yẹ̀yẹ́. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ọ̀rọ̀ eré ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó jẹ́ orin, odù irọ́, ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àti ìsọkúsọ. Èyí sì lè jẹ́ odù ifá, orin àlùjó, ọ̀rọ̀ ìròrí (philosophy) àti fíìmù (tíátà).