Ayatul Kursi

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُۚ لَا تَأۡخُذُهُۥ سِنَةٞ وَلَا نَوۡمٞۚ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ مَن ذَا ٱلَّذِي يَشۡفَعُ عِندَهُۥٓ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيۡءٖ مِّنۡ عِلۡمِهِۦٓ إِلَّا بِمَا شَآءَۚ وَسِعَ كُرۡسِيُّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۖ وَلَا يَـُٔودُهُۥ حِفۡظُهُمَاۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ ٢٥٥

Allāhu lā ilāha illā huwal-hayyul-qayyūmu lā ta'khudhuhū sinatun walā nawmul lahū mā fis-samāwāti wamā fil-ardi man dhal-ladhī yashfa'u 'indahū illā bi idhnihī ya'lamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum walā yuhītūna bishay'im min 'ilmihī illā bimā shā'a wasi'a kursiyyuhus-samāwāti wal-arda walā ya'ūduhū hifzuhumā wahuwal-'aliyyul-'azīm

Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀?1 Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.2 Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi.3

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:48. [2] Ọ̀nà méjì ni “kursiyy” tó jẹyọ nínú gbólóhùn yìí “Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.” túmọ̀ sí. Ìtúmọ̀ kìíní ni pé, “kursiyy” túmọ̀ sí àga gẹ́gẹ́ bí mo ṣe túmọ̀ rẹ̀ sókè yẹn. Ìtúmọ̀ kejì ni pé, “kursiyy” túmọ̀ sí ibùgbẹ́sẹ̀lé Allāhu - tó ga jùlọ - ìyẹn ni pé, àyè tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì le. Àpapọ̀ ìtúmọ̀ kìíní kejì ni pé, Allāhu gúnwà sí orí “al-‘Arṣ” ìtẹ́ ọlá Rẹ̀. Ó sì gbé ẹsẹ̀ Rẹ̀ méjèèjì lé orí “al-kursiyy” àga Rẹ̀. Àgá náà sì fẹjú ju àpapọ̀ àwọn sánmọ̀ méjèèjè àti àwọn ilẹ̀ méjèèjè. [3] Ọ̀kan pàtàkì nínú āyah ìṣọ́ tó nípọn ju ẹ̀wù irin ni āyah al-Kursiyy.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Ka gbogbo Suratu Al-Baqarah

Àwọn ìbéèrè

Níbo ni Ayatul Kursi wà nínú Al-Kurani?

Ayatul Kursi wà nínú Suratu Al-Baqarah, 2:255.