وَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ فَإِنَّكَ بِأَعۡيُنِنَاۖ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ حِينَ تَقُومُ ٤٨
Wasbir lihukmi rabbika fa innaka bi a'yuninā wasabbih bihamdi rabbika hīna taqūm
Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Nínú Sunan Abī Dāwud, láti ọ̀dọ̀ bàbá Barzah ’Azlamiy - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ń sọ ní ìparí nígbà tí ó bá fẹ́ dìde kúrò lórí ìjókòó, « سُبْحَانَكَ اللَّهُمَّ وَبِحَمْدِكَ أَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلاَّ أَنْتَ أَسْتَغْفِرُكَ وَأَتُوبُ إِلَيْكَ ». “Subhānaka-llahummọ wabihamdika ’aṣhadu ’anlā ’ilāha ’illā ’anta ’astagfiruka wa ’atūbu ’ilaek” (Mímọ́ ni fún Allāhu, ẹyìn sì ni fún Ọ. Mò ń jẹ́rìí pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ. Mò ń tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ, mo sì ń ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ.) Ọkùnrin kan sọ pé, “Òjíṣẹ́ Allāhu, dájúdájú o sọ ọ̀rọ̀ kan tí o kì í sọ tẹ́tẹ̀tẹ́lẹ̀?” Ó sọ pé, “Pípa-ẹ̀ṣẹ̀-rẹ́ ni fún n̄ǹkan tí ó bá ṣẹlẹ̀ ní ìjókòó.” Albāniy sọ pé, “Ó dára, ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.”