Suratu At-Taghabun, aaya 9

64:9

يَوۡمَ يَجۡمَعُكُمۡ لِيَوۡمِ ٱلۡجَمۡعِۖ ذَٰلِكَ يَوۡمُ ٱلتَّغَابُنِۗ وَمَن يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ وَيَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا يُكَفِّرۡ عَنۡهُ سَيِّـَٔاتِهِۦ وَيُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ٩

Yawma yajma'ukum liyawmil-jam'i dhālika yawmut-taghābuni waman yu'mim billāhi waya'mal sālihan yukaffir 'anhu sayyi'ātihī wayudkhilhu jannātin tajrī min tahtihal-anhāru khālidīna fīhā abadan dhālikal-fawzul-'azīm

Ní ọjọ́ tí (Allāhu) yóò ko yín jọ fún ọjọ́ àkójọ. Ìyẹn ni ọjọ́ èrè àti àdánù.1 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba Allāhu gbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (Allāhu) yóò pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ fún un. Ó sì máa mú un wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ títí láéláé. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Lára orúkọ ọjọ́ àjíǹde ni Ọjọ́ Èrè àti Àdánù. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo yó jèrè Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn aláìgbàgbọ́ sì máa pàdánù rẹ̀.