وَمَا ٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِيهِ مِن شَيۡءٖ فَحُكۡمُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبِّي عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ ١٠
Wamakhtalaftum fīhi min shay'in fahukmuhū ilallāhi dhālikumullāhu rabbī 'alayhi tawakkaltu wa ilayhi unīb
Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà). 1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pe, kí á ṣẹ́rí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyapa-ẹnu bá wáyé lórí wọn sínú al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀.