Suratu As-Saffat, aaya 113

37:113

وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٞ وَظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٞ ١١٣

Wabāraknā 'alayhi wa'alā ishāqa wamin dhurriyyatihimā muhsinun wazālimul linafsihī mubīn

Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé: (ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a -; (ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni ẹni tí Allāhu Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jọ́sìn fún Òun; (ìkẹta) Kò sí ohun tó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún.