Suratu Ar-Rum, aaya 30

30:30

فَأَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗاۚ فِطۡرَتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي فَطَرَ ٱلنَّاسَ عَلَيۡهَاۚ لَا تَبۡدِيلَ لِخَلۡقِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ ٣٠

Fa aqim wajhaka lid-dīni hanīfan fitratallāhil-latī fataran-nāsa 'alayhā lā tabdīla likhalqillāhi dhālikad-dīnul-qayyimu walākinna aktharan-nāsi lā ya'lamūn

Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn Islām, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sí ìyípadà fún ẹ̀sìn Allāhu.1 (ìyẹn ni pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ yí ẹ̀sìn Allāhu padà.)2 Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.3

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 “Ẹ̀dá Allāhu” nínú āyah yìí dúró fún “ẹ̀sìn Allāhu” ní ìbámu sí sàkánì tí ó ti jẹyọ. [2] Àwọn onítírà yapa àṣẹ yìí, wọ́n sì sọra wọn di yẹ̀húdí àti nasọ̄rọ̄. Àwọn mìíràn tún sọra wọn di ọ̀ṣẹbọ. A dúpẹ́ fún Allāhu tí Ó mú wa dúró ṣinṣin sórí ẹ̀sìn Rẹ̀ ’Islām. [3] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:105.