Suratu Ar-Ra'd, aaya 38

13:38

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَذُرِّيَّةٗۚ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ لِكُلِّ أَجَلٖ كِتَابٞ ٣٨

Walaqad arsalnā rusulam min qablika waja'alnā lahum azwājan wadhurriyyatan wamā kāna lirasūlin an ya'tiya bi'āyatin illā bi idhnillāhi likulli ajalin kitāb

Dájúdájú A ti rán àwọn Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. A sì fún wọn ní àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọọmọ.1 Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Òjíṣẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu.2 Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ló ní àkọsílẹ̀.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Āyah yìí kò kó ikú Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - sínú. Ìdí nìyí tí àwọn hadīth tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fi yanjú ọ̀rọ̀ ìpadàbọ̀ rẹ̀ lọ́tọ̀. [2] “àmì kan” nínú āyah yìí dúró fún ìyà kan tàbí ìparun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún àwọn aláìgbàgbọ́ nínú Òjíṣẹ́ náà.