Suratu An-Nisa, aaya 97

4:97

إِنَّ ٱلَّذِينَ تَوَفَّىٰهُمُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ ظَالِمِيٓ أَنفُسِهِمۡ قَالُواْ فِيمَ كُنتُمۡۖ قَالُواْ كُنَّا مُسۡتَضۡعَفِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ قَالُوٓاْ أَلَمۡ تَكُنۡ أَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٗ فَتُهَاجِرُواْ فِيهَاۚ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرًا ٩٧

Innal-ladhīna tawaffāhumul-malā'ikatu zālimī anfusihim qālū fīma kuntum qālū kunnā mustad'afīna fil-ardi qālū alam takun ardullāhi wāsi'atan fatuhājirū fīhā fa ulā'ika ma'wāhum jahannamu wasā'at masīrā

Dájúdájú àwọn tí mọlāika gba ẹ̀mí wọn, (lásìkò) tí wọ́n ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, (àwọn mọlāika) sọ pé: “Kí ni ẹ̀ ń ṣe (nínú ẹ̀sìn)?1” Wọ́n wí pé: “Wọ́n dá wa lágara lórí ilẹ̀ ni.” (Àwọn mọlāika) sọ pé: “Ṣé ilẹ̀ Allāhu kò fẹ̀ tó (fún yín) láti gbé ẹ̀sìn yín sá lórí ilẹ̀?” Àwọn wọ̀nyẹn, iná Jahanamọ ni ibùgbé wọn. Ó sì burú ní ìkángun.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Tàbí “nínú igun wo ni ẹ wà, igun àwọn mùsùlùmí ni tàbí igun àwọn ọ̀ṣẹbọ? Tàbí nínú ìlú wo ni ẹ wà, ìlú 'Islām ni tàbí ìlú ọ̀ṣẹbọ? ”