وَإِنۡ أَرَدتُّمُ ٱسۡتِبۡدَالَ زَوۡجٖ مَّكَانَ زَوۡجٖ وَءَاتَيۡتُمۡ إِحۡدَىٰهُنَّ قِنطَارٗا فَلَا تَأۡخُذُواْ مِنۡهُ شَيۡـًٔاۚ أَتَأۡخُذُونَهُۥ بُهۡتَٰنٗا وَإِثۡمٗا مُّبِينٗا ٢٠
Wa in arattumustibdāla zawjim makāna zawjin wa ātaytum ihdāhunna qintāran falā ta'khudhū minhu shay'an ata'khudhūnahū buhtānan wa ithmam mubīnā
Tí ẹ bá sì fẹ́ fi ìyàwó kan pààrọ̀ àyè ìyàwó kan, tí ẹ sì ti fún ọ̀kan nínú wọn ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá, ẹ ò gbọdọ̀ gba n̄ǹkan kan nínú rẹ̀ mọ́. Ṣé ẹ̀yin yóò gbà á ní ti àdápa irọ́ (tí ẹ̀ ń pa mọ́ wọn) àti ẹ̀ṣẹ̀ tó fojú hàn(tí ẹ̀ ń dá nípa wọn)?1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Pípa irọ́ mọ́ ìyàwó ẹni àti fífi ìnira kàn án nítorí kí ó lè sọ pé òun kò ṣe mọ́, - ṣebí ọkọ kúkú ti mọ̀ pé bí ìkọ̀sílẹ̀ bá wáyé láti ọ̀dọ̀ obìnrin, èyí tí a mọ̀ sí kul‘u, ó máa dá sọ̀daàkí rẹ̀ padà fún ọkọ - ó jẹ́ ìṣesí burúkú tí āyah yìí ń ṣe ní harām.