Suratu An-Nisa, aaya 171

4:171

يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا تَغۡلُواْ فِي دِينِكُمۡ وَلَا تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّۚ إِنَّمَا ٱلۡمَسِيحُ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ رَسُولُ ٱللَّهِ وَكَلِمَتُهُۥٓ أَلۡقَىٰهَآ إِلَىٰ مَرۡيَمَ وَرُوحٞ مِّنۡهُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرُسُلِهِۦۖ وَلَا تَقُولُواْ ثَلَٰثَةٌۚ ٱنتَهُواْ خَيۡرٗا لَّكُمۡۚ إِنَّمَا ٱللَّهُ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ سُبۡحَٰنَهُۥٓ أَن يَكُونَ لَهُۥ وَلَدٞۘ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا ١٧١

Yā'ahlal-kitābi lā taghlū fī dīnikum walā taqūlū 'alallāhi illal-haqqa innamal-masīhu 'īsabnu maryama rasūlullāhi wakalimatuhū alqāhā ilā maryama warūhum minhu fa'āminū billāhi warusulihī walā taqūlū thalāthatunintahū khayral lakum innamallāhu ilāhun wāhidun subhānahū an yakūna lahū waladul lahū mā fis-samāwāti wamā fil-ardi wakafā billāhi wakīlā

Ẹ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, kí ẹ sì má sọ ohun kan nípa Allāhu àfi òdodo. Òjíṣẹ́ Allāhu ni Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni (Ó fi dá Mọsīh ‘Īsā ọmọ Mọryam). Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹ yé sọ mẹ́ta (lọ́kan) mọ́. Kí ẹ jáwọ́ níbẹ̀ ló jẹ́ oore fún yín. Allāhu nìkan ni Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Ó mọ́ tayọ kí Ó ní ọmọ. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì tó ní Alámòjúútó.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Kíyè sí i, “mọsīh” nínú èdè Lárúbáwá kò túmọ̀ sí olùgbàlà. “kalmọtu-llāh” túmọ̀ sí ẹni tí Allāhu fi ọ̀rọ̀ "kunfayakūn" dá. “Rūhu-llāh” túmọ̀ sí ẹni tí Allāhu fi atẹ́gùn ẹ̀mí mímọ́ dá.