Suratu An-Nisa, aaya 17

4:17

إِنَّمَا ٱلتَّوۡبَةُ عَلَى ٱللَّهِ لِلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسُّوٓءَ بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِن قَرِيبٖ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا ١٧

Innamat-tawbatu 'alallāhi lilladhīna ya'malūnas-sū'a bijahālatin thumma yatūbūna min qarībin fa ulā'ika yatūbullāhu 'alayhim wakānallāhu 'alīman hakīmā

Ìronúpìwàdà tí Allāhu yóò gbà ni ti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan.1 Lẹ́yìn náà, wọ́n ronú pìwàdà láìpẹ́ (ìyẹn ṣíwájú ọjọ́ ikú wọn). Àwọn wọ̀nyí ni Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ṣíṣe aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan ni ṣíṣe aburú nígbà tí ènìyàn kò nímọ̀ nípa ìdàjọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kódà kí ènìyàn ní ìmọ̀, bí ó bá ṣiṣẹ́ aburú, kì í ṣe ìmọ̀ ló pàṣẹ aburú fún, ó ti wọ aṣọ àìmọ̀kan, ó sì ṣe aburú náà pẹ̀lú àìmọ̀kan tàbí ó ṣe aburú náà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ̀kan.