وَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكَ وَرَحۡمَتُهُۥ لَهَمَّت طَّآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ أَن يُضِلُّوكَ وَمَا يُضِلُّونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡۖ وَمَا يَضُرُّونَكَ مِن شَيۡءٖۚ وَأَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَعَلَّمَكَ مَا لَمۡ تَكُن تَعۡلَمُۚ وَكَانَ فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكَ عَظِيمٗا ١١٣
Walawlā fadlullāhi 'alayka warahmatuhū lahammat tā'ifatum minhum an yudillūka wamā yudillūna illā anfusahum wamā yadurrūnaka min shay'in wa anzalallāhu 'alaykal-kitāba wal-hikmata wa'allamaka mā lam takun ta'lamu wakāna fadlullāhi 'alayka 'azīmā
Tí kì í bá ṣe ti oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ tí ń bẹ lórí rẹ ni, igun kan nínú wọn ìbá ti gbèrò láti ṣì ọ́ lọ́nà. Wọn kò sì níí ṣi ẹnì kan lọ́nà àfi ẹ̀mí ara wọn. Wọn kò sì lè fi n̄ǹkan kan kó ìnira bá ọ. Allāhu sì sọ Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah) kalẹ̀ fún ọ. Ó tún fi ohun tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ mọ̀ ọ́;1 oore àjùlọ Allāhu lórí rẹ jẹ́ ohun tó tóbi.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:52.