وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّمَّا خَلَقَ ظِلَٰلٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡجِبَالِ أَكۡنَٰنٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ سَرَٰبِيلَ تَقِيكُمُ ٱلۡحَرَّ وَسَرَٰبِيلَ تَقِيكُم بَأۡسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ يُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُسۡلِمُونَ ٨١
Wallāhu ja'ala lakum mimmā khalaqa zilālan waja'ala lakum minal-jibāli aknānan waja'ala lakum sarābīla taqīkumul-harra wasarābīla taqīkum ba sakum kadhālika yutimmu ni'matahū 'alaykum la'allakum tuslimūn
Allāhu ṣe àwọn ibòji fún yín láti ara àwọn n̄ǹkan tí Ó dá. Ó ṣe àwọn ibùgbé fún yín láti ara àwọn àpáta. Ó tún ṣe àwọn aṣọ fún yín tó ń dáàbò bò yín lọ́wọ́ ooru àti àwọn aṣọ tó ń dáàbò bò yín lójú ogun yín.1 Báyẹn l’Ó ṣe ń pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ le yín lórí nítorí kí ẹ lè jẹ́ mùsùlùmí.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àpẹ̀ẹrẹ aṣọ tó ń dáàbò bo ẹ̀dá lójú ogun ni ẹ̀wù irin tí kì í jẹ́ kí ọfà wọlé sínú ara. Àwọn aṣọ ààbò ogun wọ̀nyí kò túmọ̀ sí aṣọ òògùn bíi bàǹtẹ́ òògùn fún ààbò lójú ogun. Irúfẹ́ àwọn aṣọ òògùn wọ̀nyí jẹ́ èèwọ̀ ẹ̀sìn nítorí pé, wọn kò là níbi ṣíṣe ẹbọ àti wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ àlùjànnú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lo irúfẹ́ aṣọ òògùn yìí sì ti sọ ara rẹ̀ di ọ̀ṣẹbọ.