بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ عَدُوِّي وَعَدُوَّكُمۡ أَوۡلِيَآءَ تُلۡقُونَ إِلَيۡهِم بِٱلۡمَوَدَّةِ وَقَدۡ كَفَرُواْ بِمَا جَآءَكُم مِّنَ ٱلۡحَقِّ يُخۡرِجُونَ ٱلرَّسُولَ وَإِيَّاكُمۡ أَن تُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ رَبِّكُمۡ إِن كُنتُمۡ خَرَجۡتُمۡ جِهَٰدٗا فِي سَبِيلِي وَٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِيۚ تُسِرُّونَ إِلَيۡهِم بِٱلۡمَوَدَّةِ وَأَنَا۠ أَعۡلَمُ بِمَآ أَخۡفَيۡتُمۡ وَمَآ أَعۡلَنتُمۡۚ وَمَن يَفۡعَلۡهُ مِنكُمۡ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ ١
Yā'ayyuhal-ladhīna āmanū lā tattakhidhū 'aduwwī wa'aduwwakum awliyā'a tulqūna ilayhim bil-mawaddati waqad kafarū bimā jā'akum minal-haqqi yukhrijūnar-rasūla wa iyyākum an tu'minū billāhi rabbikum in kuntum kharajtum jihādan fī sabīlī wabtighā'a mardātī tusirrūna ilayhim bil-mawaddati wa ana a'lamu bimā akhfaytum wamā a'lantum waman yaf'alhu minkum faqad dalla sawā'as-sabīl
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun ní ojú-ọ̀nà Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.
إِن يَثۡقَفُوكُمۡ يَكُونُواْ لَكُمۡ أَعۡدَآءٗ وَيَبۡسُطُوٓاْ إِلَيۡكُمۡ أَيۡدِيَهُمۡ وَأَلۡسِنَتَهُم بِٱلسُّوٓءِ وَوَدُّواْ لَوۡ تَكۡفُرُونَ ٢
In yathqafūkum yakūnū lakum a'dā'an wayabsutū ilaykum aydiyahum wa alsinatahum bis-sū'i wawaddū law takfurūn
Tí ọwọ́ wọn bá bà yín, wọ́n máa di ọ̀tá fún yín. Wọn yó sì fi ọwọ́ wọn àti ahọ́n wọn nawọ́ aburú si yín. Wọ́n sì máa fẹ́ kí ó jẹ́ pé ẹ di aláìgbàgbọ́.
لَن تَنفَعَكُمۡ أَرۡحَامُكُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُكُمۡۚ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَفۡصِلُ بَيۡنَكُمۡۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ٣
Lan tanfa'akum arhāmukum walā awlādukum yawmal-qiyāmati yafsilu baynakum wallāhu bimā ta'malūna basīr
Àwọn ẹbí yín àti àwọn ọmọ yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní; ní Ọjọ́ Àjíǹde ni Allāhu máa ṣèpínyà láààrin yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
قَدۡ كَانَتۡ لَكُمۡ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ فِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ إِذۡ قَالُواْ لِقَوۡمِهِمۡ إِنَّا بُرَءَٰٓؤُاْ مِنكُمۡ وَمِمَّا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ كَفَرۡنَا بِكُمۡ وَبَدَا بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُ ٱلۡعَدَٰوَةُ وَٱلۡبَغۡضَآءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥٓ إِلَّا قَوۡلَ إِبۡرَٰهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسۡتَغۡفِرَنَّ لَكَ وَمَآ أَمۡلِكُ لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۖ رَّبَّنَا عَلَيۡكَ تَوَكَّلۡنَا وَإِلَيۡكَ أَنَبۡنَا وَإِلَيۡكَ ٱلۡمَصِيرُ ٤
Qad kānat lakum uswatun hasanatun fī ibrāhīma walladhīna ma'ahū idh qālū liqawmihim innā bura'ā'u minkum wamimmā ta'budūna min dūnillāhi kafarnā bikum wabadā baynanā wabaynakumul-'adāwatu wal-baghdā'u abadan hattā tu'minū billāhi wahdahū illā qawla ibrāhīma li abīhi la astaghfiranna laka wamā amliku laka minallāhi min shay'ir rabbanā 'alayka tawakkalnā wa ilayka anabnā wa ilaykal-masīr
Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. - Àfi ọ̀rọ̀ tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo máa tọrọ àforíjìn fún ọ, èmi kò sì ní ìkápá kiní kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu. - Olúwa wa, Ìwọ l’a gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ l’a ṣẹ́rí padà sí (nípa ìronúpìwàdà). Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.
رَبَّنَا لَا تَجۡعَلۡنَا فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ وَٱغۡفِرۡ لَنَا رَبَّنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ٥
Rabbanā lā taj'alnā fitnatal lilladhīna kafarū waghfir lanā rabbanā innaka antal-'azīzul-hakīm
Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.1 Foríjìn wá, Olúwa wa. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”
لَقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِيهِمۡ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَۚ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ ٦
Laqad kāna lakum fīhim uswatun hasanatul liman kāna yarjullāha wal-yawmal-ākhira waman yatawalla fa innallāha huwal-ghaniyyul-hamīd
Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara wọn fún ẹni tó ń retí (ẹ̀sán) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí, dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.
۞ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَجۡعَلَ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَ ٱلَّذِينَ عَادَيۡتُم مِّنۡهُم مَّوَدَّةٗۚ وَٱللَّهُ قَدِيرٞۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ٧
'Asallāhu an yaj'ala baynakum wabaynal-ladhīna 'ādaytum minhum mawaddatan wallāhu qadīrun wallāhu ghafūrur rahīm
Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò fi ìfẹ́ sí ààrin ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ mú ní ọ̀tá nínú wọn (ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá di mùsùlùmí). Allāhu ni Alágbára. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
لَّا يَنۡهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ لَمۡ يُقَٰتِلُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَلَمۡ يُخۡرِجُوكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ أَن تَبَرُّوهُمۡ وَتُقۡسِطُوٓاْ إِلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ ٨
Llā yanhākumullāhu 'anil-ladhīna lam yuqātilūkum fid-dīni walam yukhrijūkum min diyārikum an tabarrūhum watuqsitū ilayhim innallāha yuhibbul-muqsitīn
Allāhu kò kọ̀ fún yín nípa àwọn tí kò gbé ogun tì yín nípa ẹ̀sìn, tí wọn kò sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, pé kí ẹ ṣe dáadáa sí wọn, kí ẹ sì ṣe déédé sí wọn. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-déédé.
إِنَّمَا يَنۡهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ قَٰتَلُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَأَخۡرَجُوكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ وَظَٰهَرُواْ عَلَىٰٓ إِخۡرَاجِكُمۡ أَن تَوَلَّوۡهُمۡۚ وَمَن يَتَوَلَّهُمۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّٰلِمُونَ ٩
Innamā yanhākumullāhu 'anil-ladhīna qātalūkum fid-dīni wa akhrajūkum min diyārikum wazāharū 'alā ikhrājikum an tawallawhum waman yatawallahum fa ulā'ika humuz-zālimūn
Ohun tí Allāhu kọ̀ fún yín nípa àwọn tó gbógun tì yín nínú ẹ̀sìn, tí wọ́n sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, tí wọ́n tún ṣe ìrànlọ́wọ́ (fún àwọn ọ̀tá yín) láti le yín jáde, ni pé (Ó kọ̀ fún yín) láti mú wọn ní ọ̀rẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا جَآءَكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ مُهَٰجِرَٰتٖ فَٱمۡتَحِنُوهُنَّۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِهِنَّۖ فَإِنۡ عَلِمۡتُمُوهُنَّ مُؤۡمِنَٰتٖ فَلَا تَرۡجِعُوهُنَّ إِلَى ٱلۡكُفَّارِۖ لَا هُنَّ حِلّٞ لَّهُمۡ وَلَا هُمۡ يَحِلُّونَ لَهُنَّۖ وَءَاتُوهُم مَّآ أَنفَقُواْۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّۚ وَلَا تُمۡسِكُواْ بِعِصَمِ ٱلۡكَوَافِرِ وَسۡـَٔلُواْ مَآ أَنفَقۡتُمۡ وَلۡيَسۡـَٔلُواْ مَآ أَنفَقُواْۚ ذَٰلِكُمۡ حُكۡمُ ٱللَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡۖ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ١٠
Yā'ayyuhal-ladhīna āmanū idhā jā'akumul-mu'minātu muhājirātin famtahinūhunnallāhu a'lamu bi īmānihinna fa in 'alimtumūhunna mu'minātin falā tarji'ūhunna ilal-kuffāri lā hunna hillul lahum walā hum yahillūna lahunna wa ātūhum mā anfaqū walā junāha 'alaykum an tankihūhunna idhā ātaytumūhunna ujūrahunna walā tumsikū bi'isamil-kawāfiri was'alū mā anfaqtum walyas'alū mā anfaqū dhālikum hukmullāhi yahkumu baynakum wallāhu 'alīmun hakīm
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá ba yín, tí wọ́n gbé ìlú àwọn aláìgbàgbọ́ jù sílẹ̀, ẹ ṣe ìdánwò fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, tí ẹ bá mọ̀ wọ́n sí onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin kò lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn.1 Ẹ fún (àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin) ní owó tí wọ́n ná (ìyẹn, owó-orí obìnrin náà). Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà pé kí ẹ fẹ́ wọn nígbà tí ẹ bá ti fún (àwọn obìnrin wọ̀nyí) ní owó-orí wọn. Ẹ má ṣe fi owó-orí àwọn obìnrin yín tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mú wọn mọ́lẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó yín láì jẹ́ pé wọ́n gba ’Islām pẹ̀lú yín).2 Ẹ bèèrè ohun tí ẹ ná (ìyẹn, owó-orí wọn lọ́wọ́ aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin tí wọ́n sá lọ bá). Kí àwọn (aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin náà) bèèrè ohun tí àwọn náà ná (ìyẹn, owó-orí wọn lọ́wọ́ ẹ̀yin tí onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin sá wá bá). Ìyẹn ni ìdájọ́ Allāhu. Ó sì ń dájọ́ láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n
وَإِن فَاتَكُمۡ شَيۡءٞ مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُمۡ إِلَى ٱلۡكُفَّارِ فَعَاقَبۡتُمۡ فَـَٔاتُواْ ٱلَّذِينَ ذَهَبَتۡ أَزۡوَٰجُهُم مِّثۡلَ مَآ أَنفَقُواْۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ أَنتُم بِهِۦ مُؤۡمِنُونَ ١١
Wa in fātakum shay'um min azwājikum ilal-kuffāri fa'āqabtum fa'ātul-ladhīna dhahabat azwājuhum mithla mā anfaqū wattaqullāhal-ladhī antum bihī mu'minūn
Tí kiní kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó yín bá bọ́ mọ yín lọ́wọ́ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, tí ẹ sì kórè ogun, ẹ fún àwọn tí ìyàwó wọn sá lọ ní irú òdiwọ̀n ohun tí wọ́n ná (ní owó-orí). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Rẹ̀.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِذَا جَآءَكَ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ يُبَايِعۡنَكَ عَلَىٰٓ أَن لَّا يُشۡرِكۡنَ بِٱللَّهِ شَيۡـٔٗا وَلَا يَسۡرِقۡنَ وَلَا يَزۡنِينَ وَلَا يَقۡتُلۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ وَلَا يَأۡتِينَ بِبُهۡتَٰنٖ يَفۡتَرِينَهُۥ بَيۡنَ أَيۡدِيهِنَّ وَأَرۡجُلِهِنَّ وَلَا يَعۡصِينَكَ فِي مَعۡرُوفٖ فَبَايِعۡهُنَّ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُنَّ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ١٢
Yā'ayyuhan-nabiyyu idhā jā'akal-mu'minātu yubāyi'naka 'alā al lā yushrikna billāhi shay'an walā yasriqna walā yaznīna walā yaqtulna awlādahunna walā ya'tīna bibuhtānin yaftarīnahū bayna aydīhinna wa arjulihinna walā ya'sīnaka fī ma'rūfin fabāyi'hunna wastaghfir lahunnallāha innallāha ghafūrur rahīm
Ìwọ Ànábì, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá bá ọ, tí wọ́n ń ṣe àdéhùn fún ọ pé àwọn kò níí fi kiní kan ṣẹbọ sí Allāhu, àwọn kò níí jalè, àwọn kò níí ṣe sìná, àwọn kò níí pa ọmọ wọn, àwọn kò níí mú àdápa irọ́ wá, àdápa irọ́ tí wọ́n ń mú wá láààrin ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn (ìyẹn ni gbígbé oyún olóyún fún ọkọ wọn), àwọn kò sì níí yapa rẹ níbi n̄ǹkan dáadáa, nígbà náà bá wọn ṣe àdéhùn, kí ó sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَوَلَّوۡاْ قَوۡمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ قَدۡ يَئِسُواْ مِنَ ٱلۡأٓخِرَةِ كَمَا يَئِسَ ٱلۡكُفَّارُ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡقُبُورِ ١٣
Yā'ayyuhal-ladhīna āmanū lā tatawallaw qawman ghadiballāhu 'alayhim qad ya'isū minal-ākhirati kamā ya'isal-kuffāru min ashābil-qubūr
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ìjọ kan tí Allāhu ti bínú sí ní ọ̀rẹ́. Dájúdájú wọ́n ti sọ̀rètí nù nípa ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó wà nínú sàréè (ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́).
Àwọn nọ́mbà àlàyé ìsàlẹ̀ máa ń mú ọ lọ sí ojú-ewé aaya náà, níbi tí àlàyé olùtúmọ̀ wà.
Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.