Suratu Al-Ma'idah, aaya 114

5:114

قَالَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ ٱللَّهُمَّ رَبَّنَآ أَنزِلۡ عَلَيۡنَا مَآئِدَةٗ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ تَكُونُ لَنَا عِيدٗا لِّأَوَّلِنَا وَءَاخِرِنَا وَءَايَةٗ مِّنكَۖ وَٱرۡزُقۡنَا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ ١١٤

Qāla 'īsabnu maryamallāhumma rabbanā anzil 'alaynā mā'idatam minas-samā'i takūnu lanā 'īdal li awwalinā wa ākhirinā wa āyatam minka warzuqnā wa anta khayrur-rāziqīn

‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: “Allāhu, Olúwa wa, sọ ọpọ́n oúnjẹ kan kalẹ̀ fún wa láti inú sánmọ̀, kí ó jẹ́ ọdún fún ẹni àkọ́kọ́ wa àti ẹni ìkẹ́yìn wa.1 Kí ó sì jẹ́ àmì kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Pèsè fún wa, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.”2

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, ọjọ́ náà máa di ọjọ́ ọdún fún ìjọ Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò tirẹ̀ ti lọ. [2] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah as-Sọ̄ffāt; 37:125.