Suratu Al-Imran, aaya 39

3:39

فَنَادَتۡهُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَهُوَ قَآئِمٞ يُصَلِّي فِي ٱلۡمِحۡرَابِ أَنَّ ٱللَّهَ يُبَشِّرُكَ بِيَحۡيَىٰ مُصَدِّقَۢا بِكَلِمَةٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَسَيِّدٗا وَحَصُورٗا وَنَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ ٣٩

Fanādathul-malā'ikatu wahuwa qā'imun yusallī fil-mihrābi annallāha yubasshiruka biyahyā musaddiqā bikalimatim minallāhi wasayyidan wahasūran wanabiyyam minas-sālihīn

Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): “Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu.1 (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin.2 (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 “Ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu”, ìyẹn ni pé, ẹni tí Allāhu fi "kunfayakun" ṣẹ̀dá rẹ̀. [2] tàbí ẹni tí kò ju ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ìfẹ́-inú àti yòdòyìndìn ayé.