إِن يَمۡسَسۡكُمۡ قَرۡحٞ فَقَدۡ مَسَّ ٱلۡقَوۡمَ قَرۡحٞ مِّثۡلُهُۥۚ وَتِلۡكَ ٱلۡأَيَّامُ نُدَاوِلُهَا بَيۡنَ ٱلنَّاسِ وَلِيَعۡلَمَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَيَتَّخِذَ مِنكُمۡ شُهَدَآءَۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلظَّٰلِمِينَ ١٤٠
In yamsaskum qarhun faqad massal-qawma qarhum mithluhū watilkal-ayyāmu nudāwiluhā baynan-nāsi waliya'lamallāhul-ladhīna āmanū wayattakhidha minkum shuhadā'a wallāhu lā yuhibbuz-zālimīn
Tí ìpalára kan bá kàn yín, irú ìpalára bẹ́ẹ̀ kúkú ti kan ìjọ (kèfèrí) náà. Àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, À ń yí i po láààrin àwọn ènìyàn ni. Àti pé nítorí kí Allāhu lè ṣe àfihàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti (nítorí) kí Ó lè sọ àwọn kan nínú yín di òkú ojú-ogun (ní ojú-ọ̀nà Rẹ̀)1. Allāhu kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àádọ́rin àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - ló bá ogun yìí lọ. Mẹ́rin nínú wọn jẹ́ muhājirūn. Hamzah ọmọ ‘Abdul-Muttọlib wà nínú wọn. Àwọn yòókù jẹ́ ansọ̄r - kí Allāhu yọ́nú sí gbogbo wọn -.