قُل لِّلۡمُخَلَّفِينَ مِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ سَتُدۡعَوۡنَ إِلَىٰ قَوۡمٍ أُوْلِي بَأۡسٖ شَدِيدٖ تُقَٰتِلُونَهُمۡ أَوۡ يُسۡلِمُونَۖ فَإِن تُطِيعُواْ يُؤۡتِكُمُ ٱللَّهُ أَجۡرًا حَسَنٗاۖ وَإِن تَتَوَلَّوۡاْ كَمَا تَوَلَّيۡتُم مِّن قَبۡلُ يُعَذِّبۡكُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا ١٦
Qul lil-mukhallafīna minal-a'rābi satud'awna ilā qawmin ulī ba sin shadīdin tuqātilūnahum aw yuslimūna fa in tutī'ū yu'tikumullāhu ajran hasanan wa in tatawallaw kamā tawallaytum min qablu yu'addhibkum 'adhāban alīmā
Sọ fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun nínú àwọn Lárúbáwá oko pé: “Wọ́n máa pè yín sí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní agbára ogun jíjà gan-an. Ẹ máa jà wọ́n lógun tàbí kí wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (fún ’Islām). Tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ (yìí), Allāhu yóò fún yín ní ẹ̀san tó dára. Tí ẹ̀yin bá sì pẹ̀yìndà gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe pẹ̀yìndà ṣíwájú, (Allāhu) yó sì fi ìyà ẹlẹ́ta-eléro jẹ yín.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, bí ó bá jẹ́ pé ní òtítọ́ àti ní òdodo ni ẹ̀yin munāfiki fẹ́ ja ogun ẹ̀sìn, ẹ mú sùúrù díẹ̀ ná. Ogun mìíràn ń bọ̀. Àmọ́ nígbà tí ogun mìíràn dé, wọ́n tún sá sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ìṣesí wọn.