إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلصَّٰبِـِٔينَ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ٦٢
Innal-ladhīna āmanū walladhīna hādū wan-nasārā was-sābi'īna man āmana billāhi wal-yawmil-ākhiri wa'amila sālihan falahum ajruhum 'inda rabbihim walā khawfun 'alayhim walā hum yahzanūn
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Irú āyah yìí wà nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:69 àti sūrah al-Hajj; 22:17. Āyah wọ̀nyí ń sọ nípa àwọn tó ti kú ṣíwájú ìgbédìde Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àwọn wọ̀nyẹn kò ṣe ẹbọ, wọn kò sọ Allāhu di mẹ́ta lọ́kan.