Suratu Al-Baqarah, aaya 30

2:30

وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّي جَاعِلٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ خَلِيفَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَجۡعَلُ فِيهَا مَن يُفۡسِدُ فِيهَا وَيَسۡفِكُ ٱلدِّمَآءَ وَنَحۡنُ نُسَبِّحُ بِحَمۡدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَۖ قَالَ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ٣٠

Wa idh qāla rabbuka lil-malā'ikati innī jā'ilun fil-ardi khalīfatan qālū ataj'alu fīhā man yufsidu fīhā wayasfikud-dimā'a wanahnu nusabbihu bihamdika wanuqaddisu laka qāla innī a'lamu mā lā ta'lamūn

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.”1 Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Ọ. A óò máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọ sẹ́!” Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ àrólé nítorí pé, ó jẹ́ ẹ̀dá tí yóò máa bímọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ náà yóò máa bímọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mọlāika kò sì lè jẹ́ àrólé nítorí pé, bíbí ọmọ kò sí nínú ìṣẹ̀dá tiwọn.