وَإِن طَلَّقۡتُمُوهُنَّ مِن قَبۡلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ وَقَدۡ فَرَضۡتُمۡ لَهُنَّ فَرِيضَةٗ فَنِصۡفُ مَا فَرَضۡتُمۡ إِلَّآ أَن يَعۡفُونَ أَوۡ يَعۡفُوَاْ ٱلَّذِي بِيَدِهِۦ عُقۡدَةُ ٱلنِّكَاحِۚ وَأَن تَعۡفُوٓاْ أَقۡرَبُ لِلتَّقۡوَىٰۚ وَلَا تَنسَوُاْ ٱلۡفَضۡلَ بَيۡنَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ ٢٣٧
Wa in tallaqtumūhunna min qabli an tamassūhunna waqad faradtum lahunna farīdatan fanisfu mā faradtum illā an ya'fūna aw ya'fuwal-ladhī biyadihī 'uqdatun-nikāhi wa an ta'fū aqrabu lit-taqwā walā tansawul-fadla baynakum innallāha bimā ta'malūna basīr
Tí ẹ bá sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó súnmọ́ wọn, tí ẹ sì ti sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn, ìlàjì ohun tí ẹ ti ṣòdíwọ̀n rẹ̀ ní sọ̀daàkí (ni kí ẹ fún wọn), àfi tí àwọn obìnrin náà bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀) tàbí tí ẹni tí ìtakókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀1 bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀). Kí ẹ ṣàmójú kúrò ló súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Ẹ má ṣe gbàgbé oore àjùlọ ààrin yín. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ẹni tí ìtakókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rȩ̣̀ nínú āyah yìí lè jẹ́ ọkọ tàbí aláṣẹ obìnrin torí ààrin wọn ni ìtakókó yìgì ti ń wáyé. Níwọ̀n ìgbà tí a sì ti rí “àfi tí àwọn obìnrin náà bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀)”, igun ọkọ ni ọ̀rọ̀ kàn. Wa-llāhu ’a‘lam.